Dajudaju a n ri ninu ẹ̀mí wa nnkan ti ẹnikẹni nínú wa ko lee sọ ọ, o sọ pe: “Ṣé ẹ ti ri i?” Wọn sọ pé: Bẹẹni, o sọ pe: “Iyẹn ni igbagbọ ododo ti ko rùjú

Dajudaju a n ri ninu ẹ̀mí wa nnkan ti ẹnikẹni nínú wa ko lee sọ ọ, o sọ pe: “Ṣé ẹ ti ri i?” Wọn sọ pé: Bẹẹni, o sọ pe: “Iyẹn ni igbagbọ ododo ti ko rùjú

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Àwọn eniyan wa ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn bi i leere pé: Dajudaju a n ri ninu ẹ̀mí wa nnkan ti ẹnikẹni nínú wa ko lee sọ ọ, o sọ pe: “Ṣé ẹ ti ri i?” Wọn sọ pé: Bẹẹni, o sọ pe: “Iyẹn ni igbagbọ ododo ti ko rùjú".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Àwọn ìjọ kan ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa, wọn si bi i leere nipa nnkan ti wọn n ri ninu ẹ̀mí wọn ninu awọn alamọri nla ti sisọ rẹ tobi latara biburu rẹ ati sisa wọn fun un, O sọ- Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pe: Dajudaju eyi ti ẹ ri ni igbagbọ òdodo ti ko ruju ati àmọ̀dájú ti o maa jẹ ki ẹ le kọ ohun ti èṣù n jù sinu ọkàn, ati kikọ wiwi i jade lẹ́nu, ati titobi ìyẹn ninu ẹ̀mí yin, ati pe èṣù ko ráyè ninu ọkàn yin, yatọ si ẹni ti èṣù ráyè ninu ọkan rẹ, ti ko si lee da a padà.

فوائد الحديث

Alaye lilẹ èṣù pẹlu awọn oni igbagbọ nipa pe ko kapa nnkankan afi royiroyi.

Aigbagbọ ati aigbawọle nnkan ti o n sọ sinu ẹ̀mí ninu awọn royiroyi; nitori pe o wa lati ọdọ èṣù.

Royiroyi èṣù ko lee ni olugbagbọ lara, sugbọn ki o maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi royiroyi rẹ, ki o si jawọ kuro nibi itẹsiwaju nibi ìyẹn.

Didakẹ ko lẹtọọ fun Mùsùlùmí nipa nnkan ti o ba rú u lójú ninu alamọri ẹsin rẹ, o lẹtọọ fun un lati beere nipa rẹ.

التصنيفات

Ìgbàgbọ́ ninu Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, Lilekun igbagbọ ati adinku rẹ