ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi

ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi

Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Arakunrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju ọ̀kan ninu wa n ri ninu ẹ̀mí rẹ- o n pẹ́ nǹkan náà sọ pẹ̀lú itọka- o nífẹ̀ẹ́ si ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ lọ, o wa sọ pe: “ Ọlọhun tobi Ọlọhun tobi, ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi".

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ]

الشرح

Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun, dajudaju ẹnikan ninu wa n ri alamọri kan ninu ẹ̀mí rẹ ti o wa sínú ẹ̀mí, ṣùgbọ́n o tobi láti sọ ọ jáde, débi pe o nífẹ̀ẹ́ ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ jade lọ, Bayii ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe Ọlọhun tobi ni ẹẹmeji, o si dupẹ fun Ọlọhun pe O da ete èṣù pada si royiroyi lasan.

فوائد الحديث

Alaye pe èṣù maa n retí ìkángun olugbagbọ pẹlu royiroyi; ki o le da wọn pada lati inu igbagbọ lọ si inu aigbagbọ.

Alaye lilẹ èṣù pẹlu awọn oni igbagbọ nigba ti ko lee ni ikapa afi lori royiroyi.

O tọ́ fun olugbagbọ ki o ṣẹri kuro nibi awọn royiroyi èṣù, ki o si ti i dànù.

Ṣíṣe lofin gbigbe Ọlọhun tobi nibi nnkan ti a fẹ tabi eemọ latari nnkan tabi nnkan ti o jọ ọ ninu awọn alamọri.

Ṣíṣe lofin ṣíṣe ibeere Musulumi lọdọ onimimọ nipa gbogbo nnkan ti o ba ru u loju.

التصنيفات

Ìgbàgbọ́ ninu Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, Àwọn alujannu