Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- kọ fun yin lati maa bura pẹlu awọn baba yin

Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- kọ fun yin lati maa bura pẹlu awọn baba yin

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- kọ fun yin lati maa bura pẹlu awọn baba yin", Umar sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mi ko bura pẹlu rẹ lati igba ti mo ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibẹ ni ti ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni tí ó gbé ìbúra ẹlòmíràn pẹ̀lú rẹ wa.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- kọ kuro nibi bibura pẹlu awọn baba, ẹni ti o ba fẹ búra, ko gbọdọ bura afi pẹlu Ọlọhun, ko si gbọdọ bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si i. Lẹyin naa, Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun ko bura pẹlu rẹ lati igba ti o ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibi ìyẹn, ni ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni ti o n gbé ọrọ ẹni ti o yàtọ̀ si i wa ti o bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun.

فوائد الحديث

Ṣíṣe ibura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun leewọ, o dárúkọ awọn baba ni pato, nitori pe o wa ninu awọn àṣà asiko aimọkan.

Al-halfu: Oun ni ibura pẹlu Ọlọhun tabi awọn orukọ Ọlọhun tabi awọn iroyin Ọlọhun lori àlámọ̀rí kan ninu awọn àlámọ̀rí lati kanpa mọ ọn.

Ọla ti o n bẹ fun Umar- ki Ọlọhun yọnu si i- pẹlu yiyara itẹle àṣẹ rẹ, ati didaa agbọye rẹ ati ini àṣàjẹ rẹ.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah