“Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”

“Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”

Lati ọdọ Al-Miqdam ọmọ Maadi Karib, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”.

[O ni alaafia] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye ọkan lara awọn okunfa ti o lè fun ajọṣepọ ati ifẹ lagbara laarin awọn onigbagbọ ododo, òun naa ni pe ti ẹnikẹni ba nífẹ̀ẹ́ arakunrin rẹ̀, ki o sọ fun un pe oun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fún ifẹ tó mọ́ kangá fun Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kìí ṣe ifẹ nitori anfaani aye.

A fẹ ki a maa sọ fún ẹniti a nifẹẹ nitori Ọlọhun pé a nifẹẹ rẹ̀, kí ifẹ ati irẹpọ le maa lekun si.

Ìtànkálẹ̀ ifẹ laarin awọn onigbagbọ ododo maa n fún ìjẹ́ ọmọ iya ninu ẹsin lagbara ni, ó sì maa n dáàbò bo awujọ kuro nibi tútúká ati pinpin yẹlẹyẹlẹ.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin, Awọn ẹkọ ọrọ sísọ ati didakẹ