Ẹnikẹni ninu yin o gbọdọ fi ọwọ ọtun rẹ mu nkan ọmọkunrin rẹ nigba ti o ba n tọ, ko si gbọdọ fi ọwọ rẹ ọtun ṣe imọra nibi igbọnsẹ, ko si gbọdọ fẹ atẹgun si inu ife imumi

Ẹnikẹni ninu yin o gbọdọ fi ọwọ ọtun rẹ mu nkan ọmọkunrin rẹ nigba ti o ba n tọ, ko si gbọdọ fi ọwọ rẹ ọtun ṣe imọra nibi igbọnsẹ, ko si gbọdọ fẹ atẹgun si inu ife imumi

Lati ọdọ Abu Qatāda- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹnikẹni ninu yin o gbọdọ fi ọwọ ọtun rẹ mu nkan ọmọkunrin rẹ nigba ti o ba n tọ, ko si gbọdọ fi ọwọ rẹ ọtun ṣe imọra nibi igbọnsẹ, ko si gbọdọ fẹ atẹgun si inu ife imumi».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn ẹkọ kan; nigba ti o kọ ki ọkunrin fi ọwọ ọtun rẹ gba oko re mu nigba ti o ba n tọ, ati lati mu ẹgbin kuro niwaju tabi ẹyin pẹlu ọwọ rẹ ọtun; nitori pe ọwọ ọtun wọn pese rẹ fun awọn iṣẹ rere ni, Gẹgẹ bi o ṣe kọ fun ọmọniyan lati mi sinu igba ti o fẹ mu nibẹ.

فوائد الحديث

Alaye gbigba iwaju Isilaamu ninu awọn ẹkọ ati imọtoto.

Jijina si awọn nnkan ìdọ̀tí, ti ko ba wa si ibuyẹ afi ki o ṣe e, ki o yaa jẹ pẹlu ọwọ osi.

Alaye iyi ti o n bẹ fun ọwọ ọtun ati ọla ti o n bẹ fun un lori ọwọ osi.

Pipe Sharia Isilaamu ati kikun awọn ẹkọ rẹ.

التصنيفات

Awọn ẹkọ jijẹ ati mimu, Awọn ẹkọ bibiya bukaata