إعدادات العرض
Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ
Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ
Lati ọdọ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ ẹni ti o gbe almisiki: Ninu ki o fun ọ nínú ẹ, tabi ninu ki o ra ọjà lọwọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o daa latara rẹ, ati pe ẹni ti o n fẹ iná alagbẹdẹ: Ninu ki o jo aṣọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o buru".
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Hausa Kurdî Kiswahili Português සිංහල دری অসমীয়া ไทย Tiếng Việt አማርኛ Svenska Кыргызча ગુજરાતી नेपाली Oromoo മലയാളം Română Nederlands Soomaali پښتو తెలుగు Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Malagasy Српски Moore ქართულიالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi apejuwe lelẹ fun iran meji ninu awọn eniyan: Iran akọkọ: Alabajokoo ati ọrẹ rere ti o maa tọka lọ sọ́dọ̀ Ọlọhun ati nnkan ti O yọnu si, ti o maa n ṣe iranlọwọ lori itẹle, Ati pe apejuwe rẹ da gẹgẹ bii ẹni ti o n ta almisiki, ninu ki o fun ẹ, tabi ki o ra a lọwọ rẹ, tabi ki o si gbooorun daadaa lati ọdọ rẹ. Iran keji: Alabajokoo ati ọrẹ burúkú; ti o maa n ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ti o si maa n ṣe ikunlọwọ lori dida awọn ẹṣẹ, ti waa maa ri iṣẹ buburu lọdọ rẹ, ti yoo maa ko eebu ba ẹ nitori mimu u lọrẹ ati iba iru rẹ jokoo, Iru rẹ da gẹgẹ bii alagbẹdẹ ti o n fẹ ina rẹ: ninu ki o jo aṣọ rẹ latara ẹta parapara ina rẹ ti o n fo tẹle ara wọn, tabi ki o ri oorun buruku latara asunmọ rẹ.فوائد الحديث
Nini ẹtọ fifi apejuwa le'lẹ lati sun itumọ mọ olugbọ.
Ṣiṣe lojukokoro lori ijokoo papọ pẹlu awọn olutẹle aṣẹ ati awọn ẹnirere, ati jijina sí awọn onibajẹ ati awọn oniwa buruku.