Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo

Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo

Lati ọdọ Jundub, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ní o ku ọdún márùn-ún tí ó fi maa jáde láyé, ti o ń sọ wípé: “Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo, ti emi ba ti ẹ fẹ mu ẹnikan ninu awọn ijọ mi ni ọrẹ aayo, emi i ba mu Abu Bakr ni ọrẹ aayo, ẹ gbọ o, dajudaju awọn ijọ tí wọ́n ti lọ síwájú yin a maa mú saare awọn Anabi ati awọn ẹniire inu wọn ni mọṣalaṣi, nitori naa, ẹ má ṣe mú awọn saare ni mọṣalaṣi, dajudaju emi n kọ ọ fún yín”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n fun wa ni iro nipa ipo rẹ̀ lọdọ Ọlọhun Ọba, ó n sọ pé ipo naa dé ipo ifẹ tó ga julọ, gẹgẹ bi Anabi Ibrahim – Alaafia fun un – ṣe de bẹ, nitori eyi ni Anabi fi sọ pe òun ò ni ọrẹ aayo kankan yatọ si Ọlọhun; nitori pé ọkàn oun ti kún kẹ́kẹ́ fún ìfẹ́ Ọlọhun Ọba ati gbigbe E tobi àti mímọ̀ ọ́n, nítorí náà kò sí ààyè ninu rẹ̀ fún ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí Ọlọ́hun. Tí ó bá jẹ́ pé ó ní ọ̀rẹ́ aayo ninu àwọn ẹ̀dá ni, ìbá jẹ́ Abu Bakr As-Siddiq, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i. Lẹyin naa ó ní ka sọra kuro nibi ikọja aala ninu ifẹ, gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ti ṣe sí saare awọn anabi ati awọn ẹni rere inu wọn, titi ti wọn fi sọ wọn di ọlọrun ẹbọ ti wọn n jọsin fun wọn dipo Ọlọhun Allah, ti wọn sì kọ mọṣalaṣi ati ile ijọsin sori awọn saare wọn, Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ̀ fun awọn ijọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ṣe ṣe.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fun Abu Bakr Siddiq - ki Ọlọhun yọnu si i- ati pé dajudaju oun ni ẹni tó lọ́lá jùlọ ninu awọn Sahaaba, oun ló sì lẹtọọ ju gbogbo eniyan lọ lati jẹ khalifa lẹyin iku Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).

Dajudaju kikọ mọṣalaṣi sori awọn saare jẹ́ ọ̀kan ninu awọn aburu ti awọn ìjọ tó ṣaaju ṣe.

kíkọ̀ fun wa lati mú awọn saare ni àáyè ijọsin ti ao waa maa kirun nibẹ tabi ki a maa kirun si oku ibẹ lara, ati kíkọ̀ fun wa lati kọ́ mọṣalaṣi tabi òrùlé rìbìtì sí ori awọn saare, kí ó lè jẹ́ iṣọra fun wa kuro nibi kíkó sinu ẹbọ latara iyẹn.

Iwani ní iṣọra kuro nibi àṣejù nipa awọn ẹni rere, nitori pé ó máa ń fani lọ sí inu ẹbọ ni.

Pípàtàkì ohun tí Anabi n wá wa ní isọra kuro ní idi rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigba tí ó tẹnumọ ọn ní ó ku ọjọ márùn-ún ti yio jade laye.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah, Ọla ti o n bẹ fun awọn sahaabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn-