إعدادات العرض
Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka
Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka, ti wọn ba ṣe iyẹn, wọn ti daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn kuro lọdọ mi afi pẹlu ẹtọ Isilaamu, ati pe ìṣirò iṣẹ wọn wa lọwọ Ọlọhun".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Hausa Kurdî Kiswahili Português සිංහල Svenska ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە Tiếng Việt پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or Malagasy नेपाली Čeština Oromoo Română Nederlands Soomaali తెలుగు മലയാളം ไทย Српски Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Lietuvių Shqip Wolof Українська ქართული Moore Magyarالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun pa oun láṣẹ pẹlu biba awọn ọṣẹbọ ja titi wọn fi maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti a le jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati ki wọn jẹrii ìránṣẹ́ fun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati ṣiṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti ijẹrii yii n beere fun bii sisọ awọn irun maraarun-un ni ọsan ati alẹ, ati ki wọn maa yọ saka ti o jẹ ọran-anyan fun awọn ti wọn lẹtọọ si i. Ti wọn ba ti ṣe awọn alamọri yii, dajudaju Isilaamu maa daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn, ti pipa wọn ko nii lẹtọọ afi ti wọn ba wu iwa ọdanran kan ti wọn wa maa fi lẹtọọ si pipa lori rẹ tori okùnfà idajọ Isilaamu, lẹyin naa, ni ọjọ igbedide Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa ṣe amojuto ìṣirò iṣẹ wọn nigba ti O mọ awọn kọ̀kọ̀ wọn.فوائد الحديث
Awọn idajọ, dajudaju o maa n lọ lori awọn nnkan ti wọn hàn, ati pe Ọlọhun lo maa n ṣe amojuto awọn kọkọ.
Pataki ipepe lọ sibi imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, ati pe o jẹ nnkan ti wọn maa n bẹrẹ pẹlu rẹ ninu ipepe.
Hadiisi yii ko túmọ̀ si jíjẹ awọn ọṣẹbọ nipa lori wiwọ inu Isilaamu, bi ko ṣe pe wọn ni igbalaaye lati ṣẹsa laaarin wiwọ inu Isilaamu tabi sisan isakọlẹ; ti wọn ba kọ afi pe ki wọn kọ ipepe sinu Isilaamu, ko si nnkan ti o ku ju biba wọn ja lọ ní ìbámu si awọn idajọ Isilaamu.
التصنيفات
Ẹsin Isilaamu