“Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan

“Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan

Lati ọdọ Shaddaad ọmọ Aos- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo há nǹkan méjì lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ pe: “Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan, ti ẹ ba ti fẹ pa nǹkan ki ẹ pa a dáadáa, ti ẹ ba ti fẹ du nǹkan, ki ẹ du u dáadáa, ki ẹni kọọkan yin pọ́n ọ̀bẹ rẹ ki ó mú, ki o si tètè ko ìsinmi ba nǹkan ti o fẹ dú”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe daadaa ni ọranyan le wa lori nibi gbogbo nǹkan. Dáadáa ni: Ìpayà Ọlọhun ni gbogbo ìgbà, níbi ìjọsìn fun Un, ati ṣíṣe oore, ati ki èèyàn má ṣe àwọn ẹ̀dá ni suta, ninu ìyẹn naa ni ṣíṣe dáadáa nibi pípa ati didu. Ṣíṣe dáadáa nibi pipa nigba ti a ba fẹ gba ẹsan: Pẹ̀lú sisẹṣa ọna ti o rọrun ju ti o si yára ju lati gba ẹ̀mí ẹni ti a fẹ pa. Ṣíṣe dáadáa nibi dídú nígbà tí a ba n dú nǹkan: Pẹ̀lú ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn pẹlu pípọ́n irinṣẹ naa, ki a si ma pọ́n ọn ni iwájú nǹkan ti a fẹ du ti o si n wò ó, ki a si ma dú u ni ibi tí ẹran-ọ̀sìn mìíràn wa ti o n wò ó.

فوائد الحديث

Àánú Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn si ẹ̀dá.

Pipa ati didu nǹkan dáadáa pẹ̀lú ki o jẹ ọ̀nà ti o ba òfin mu.

Pípé ṣẹria ati kiko ti o ko gbogbo oore sinu, ninu ìyẹn ni àánú ẹranko ati ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹ.

Kíkọ̀ kúrò nibi ifi ìyà jẹ ènìyàn lẹ́yìn pípa a.

Ṣiṣe gbogbo nnkan ti ìjìyà ba n bẹ nibẹ fun ẹranko ni eewọ.

التصنيفات

Didunbu nnkan, Awọn iwa ẹyin