إعدادات العرض
Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ
Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ, gbogbo ọjọ ti oorun ba ti n yọ ti o ba n ṣe deede laarin eeyan meji saara ni, ati pe ki o ran ẹnikan lọwọ l'ori nkan ọ̀gùn rẹ, boya ki o gbe e gun un tabi ki o gbe ẹru rẹ fun un lori rẹ saara ni, ati pe ọrọ daadaa saara ni, ati gbogbo igbesẹ ti o ba n gbe lọ sí ibi irun saara ni, ki o si tun maa mu nkan ti o le ṣe eeyan ni ṣuta kuro l'ọna saara ni»
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Hausa Kurdî Português සිංහල دری অসমীয়া Tiếng Việt አማርኛ Svenska ไทย Кыргызча Kiswahili ગુજરાતી नेपाली Română മലയാളം Nederlands Oromoo తెలుగు پښتو Soomaali Malagasy Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Српски Moore ქართულიالشرح
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan l'ori gbogbo musulumi ti o ni iwọ ni ọrùn ni ojoojumọ pẹlu onka gbogbo ibi tí àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara rẹ lati maa ṣe saara, ti yio ṣe e fun Ọlọhun lati fi dupẹ alaafia, ati pe o ṣe awọn ibi ipadepọ àwọn eegun rẹ ni nkan ti o jẹ ki o rọrun fun un lati ka a kò ati lati nà án, Ati pe dajudaju saara yẹn yio maa jẹ ṣiṣe pẹlu gbogbo iṣẹ daadaa patapata, ko si mọ nibi ifunni ni owo nikan, ninu rẹ naa sì ni: Deede rẹ ati atunse rẹ laarin awọn onija meji saara ni, Ati pe saara n bẹ nibi iranlọwọ rẹ fun ẹni ti o kagara nibi nkan ọ̀gùn rẹ ti waa wa gbe e gun un tabi ki o na ọwọ ẹru rẹ fún un, Ati pe ọrọ ti o daa bii iranti ati adua ati salamọ ati eyi ti o yatọ si i saara ni, Ati pe gbogbo igbesẹ kọọkan ti o ba n gbe lọ s'ibi irun saara ni, Ati pe mimu nkan ti o le ṣeni ni ṣuta kuro l'ọna saara ni.فوائد الحديث
Tito awọn eegun ọmọ Anabi Ādam ati ini alaafia rẹ ninu awọn idẹra Ọlọhun ti o tobi julọ lori rẹ ni, nitori naa eegun kọọkan bukaata si saara fun un lati dupẹ idẹra yẹn.
Ṣiṣenilojukokoro lori títún ọpẹ dú ni ojoojumọ fun aiduro awọn idẹra yẹn.
Ṣiṣenilojukokoro lori idunimọ awọn naafila ati saara ni ojoojumọ.
Ọla ti nbẹ fun ṣiṣe àtúnṣe laarin awọn eeyan.
Ṣiṣenilojukokoro lori ki ọmọniyan maa ran ọmọ-iya rẹ lọwọ; torí pé iranlọwọ rẹ fun un saara ni.
Ṣiṣenilojukokoro lori kiki janmọọn ati ririn lọ síbẹ̀, ati yiye awọn masalasi pẹlu ìyẹn.
Ijẹ dandan ṣiṣe apọnle awọn oju-ọna awọn musulumi pẹlu jijina si nkan ti o le ṣe wọn ni ṣuta tabi ko inira ba wọn.