Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ

Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ, ẹ ma ṣe maa ọ̀nà láti tu ihoho ara yin sita, ki ẹ si ma maa tọpinpin ara yin, ki ẹ si ma maa ṣe keeta ara yín, ki ẹ si ma maa kọ ẹyin si ara yin, ki ẹ si ma maa korira ara yín, ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n kọ o si n kilọ kuro nibi awọn kan ninu nnkan ti o le bi opinya ati ọta laaarin awọn Musulumi, Ninu ìyẹn ni: (Az zonnu) oun ni ikẹfin ti o maa n ṣẹlẹ̀ ninu ọkan laini ẹri; o si ṣàlàyé pe o wa ninu eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ. Ati kuro nibi (At tahassus): Oun ni wiwadii nipa awọn ihoho awọn eniyan pẹlu oju tabi etí. Ati (At-tajassus): Oun ni wiwadii nipa nnkan ti o pamọ ninu awọn alamọri, ibi tí wọ́n ti maa n sọ ìyẹn ju ni nibi aburú. Ati kuro nibi: (Al hasad) oun ni ikorira ṣiṣẹlẹ idẹra fun awọn ẹlomiran. Ati kuro nibi (At tadaabur) ki awọn kan ninu wọn maa gbúnrí kúrò lọ́dọ̀ awọn kan, ko nii salamọ, ko si nii ṣe abẹwo ọmọ-iya rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí, Ati kuro nibi: (At tabaagud) ati ikorira ati jíjìnnà-sini, gẹgẹ bii fifi suta kan awọn ẹlomiran, ati lile oju ati aima pade ara ẹni dáadáa. Lẹyin naa, o sọ gbolohun ṣókí kan ti o ko nǹkan ti o pọ sínú ti o maa tun awọn isẹsi awọn Musulumi ṣe pẹlu ara wọn: (ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya) Ati pe ìjẹ́ ọmọ iya jẹ asopọ kan ti awọn ajọṣepọ laaarin awọn eniyan fi maa n lẹ̀ pọ̀, ti o maa n lekun ifẹ ati irẹpọ láàárín wọn.

فوائد الحديث

Aba dida burúkú ko ki n ko inira ba ẹni ti awọn ami rẹ ba han lara rẹ, o wa jẹ dandan fun olugbagbọ lati jẹ ẹni ti o gbọn ninu ati lẹyin ti ko nii gba ẹtanjẹ pẹlu awọn ẹni buruku ati awọn pooki.

Nǹkan ti a gba lero ni ikilọ kúrò nibi kikẹfin ti o maa n rinlẹ ninu ẹmi, ati titaku lori rẹ, sugbọn eyi ti o maa n ṣẹlẹ̀ ninu ẹmi ti ko rinlẹ, eleyii wọn ko la a bọ ọ lọrun.

Ṣíṣe awọn okunfa ìkórìíra-ara-ẹni ati opinya laaarin ẹni kọọkan ninu àwùjọ Musulumi leewọ, bii itọpinpin ati keeta ati nnkan ti o jọ mejeeji.

Asọtẹlẹ pẹlu biba Musulumi lo ni ibalo ọmọ iya nibi igbani ni ìmọ̀ràn ati ini ifẹ ara ẹni.

التصنيفات

Awọn iwa eebu