إعدادات العرض
Gbogbo yín ni adaranjẹ, ẹni ti a maa beere awọn ti o dajẹ lọwọ rẹ ni ẹni kọọkan yín,
Gbogbo yín ni adaranjẹ, ẹni ti a maa beere awọn ti o dajẹ lọwọ rẹ ni ẹni kọọkan yín,
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ 'Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Gbogbo yín ni adaranjẹ, ẹni ti a maa beere awọn ti o dajẹ lọwọ rẹ ni ẹni kọọkan yín,, adari fun awọn eniyan jẹ adaranjẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ọkunrin ni adaranjẹ lori awọn ara ile rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, obinrin ni adaranjẹ lori ilẹ baale rẹ ati ọmọ rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ẹru jẹ adaranjẹ lori dukia olowo rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa rẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ́, gbogbo yin ni adaranjẹ ati pe gbogbo yin ni wọn maa bi leere nipa ẹni ti o dajẹ".
الترجمة
العربية Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tagalog ئۇيغۇرچە Hausa Kurdî Português සිංහල Русский Svenska ગુજરાતી አማርኛ Tiếng Việt Kiswahili پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or Malagasy नेपाली Čeština Oromoo Română Nederlands Soomaali తెలుగు ไทย മലയാളം Српски Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Lietuvių Wolof Українська ქართული Magyar Mooreالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ojúṣe kan jẹ dandan fun gbogbo Musulumi ni awujọ ti o ma maa ṣọ ọ ti o si maa gbe e ru, Imam ati adari jẹ adaranjẹ nibi nnkan ti Ọlọhun fi wọn ṣọ́, sisọ awọn ofin wọn jẹ dandan fun un, ati didaabo bo wọn kuro lọdọ ẹni ti o ba ṣe abosi si wọn, ati gbigbe ogun ti ọta wọn, ati aima ra awọn ẹtọ wọn lare, Ati pe ọkunrin nipa awọn ara ile rẹ jẹ ẹni ti ninawo fun wọn jẹ dandan le e lori, ati biba wọn lo daadaa, ati kikọ wọn nimọ ati kikọ wọn lẹkọọ, Ati obinrin ninu ile ọkọ rẹ jẹ adaranjẹ pẹlu didari ile rẹ daadaa, ati titọ awọn ọmọ rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa ìyẹn, Ati pe ọmọ ọdọ ti o jẹ ẹrú ati alagbaṣe jẹ adaranjẹ nibi dukia olowo rẹ pẹlu sisọ nnkan ti o n bẹ lọwọ rẹ lati ọdọ rẹ, ati sinsin in, oun ni wọn maa bi leere nipa ìyẹn, Ati pe gbogbo olúkúlùkù ni adaranjẹ nibi nnkan ti wọn fi ṣọ́, ati pe gbogbo olúkúlùkù ni wọn maa bi leere nipa ẹni ti o n dajẹ.فوائد الحديث
Ojúṣe ninu àwùjọ ti musulumi jẹ gbogboogbo, oníkálukú pẹ̀lú bi o ba ṣe mọ ni ati ikapa rẹ ati ojúṣe rẹ.
Titobi ojúṣe obinrin, ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ pẹlu ṣíṣe iwọ ile ọkọ rẹ ati awọn ojúṣe rẹ si awọn ọmọ rẹ.