“Ẹni kan kan ninu yin ko nii gbagbọ ni ododo titi ti yoo fi nífẹ̀ẹ́ mi ju baba rẹ, ati ọmọ rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ lọ”

“Ẹni kan kan ninu yin ko nii gbagbọ ni ododo titi ti yoo fi nífẹ̀ẹ́ mi ju baba rẹ, ati ọmọ rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ lọ”

Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni kan kan ninu yin ko nii gbagbọ ni ododo titi ti yoo fi nífẹ̀ẹ́ mi ju baba rẹ, ati ọmọ rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ lọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe Musulumi ko nii jẹ ẹni tí igbagbọ rẹ pe titi ti yoo fi ti ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣáájú ìfẹ́ ìyá rẹ, ati baba rẹ, ati ọmọkùnrin rẹ, ati ọmọbìnrin rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ, ìfẹ́ yii n beere fun itẹle e ati riran an lọ́wọ́, ati ki èèyàn ma yapa rẹ.

فوائد الحديث

Dandan ni níní ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati titi i ṣáájú ìfẹ́ gbogbo ẹ̀dá.

Lara ami pípé ìfẹ́ ni: Ríran sunna ojiṣẹ Ọlọhun lọ́wọ́, ati níná ẹ̀mí ati dúkìá tori rẹ.

Ifẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n beere fun itẹle e nibi àṣẹ ti o ba pa, ati gbigba a ni olódodo nibi ohun ti o ba sọ, ati jíjìnnà si ohun ti o ba kọ̀, ati itẹle e, ati fifi adadaalẹ sílẹ̀.

Ẹ̀tọ́ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tobi o si kanpá ju ti gbogbo èèyàn lọ; torí pé o jẹ okùnfà imọna wa kúrò nibi anù, ati yíyọ wa kuro nibi iná, ati wiwọ alujanna.

التصنيفات

Awọn iṣẹ ọkan