“Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”

“Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”

Lati ọdọ ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”.

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹni ti o ba kọ́ imọ ìràwọ̀, ati fifi lílọ-bíbọ̀ rẹ, ati ìwọlé rẹ, ati ìjáde rẹ ṣe itọka si awọn ìṣẹ̀lẹ̀ orí ilẹ̀, bii ikú lagbaja, tabi iṣẹmi rẹ, tàbí àìsàn rẹ, ati nǹkan ti o jọ ìyẹn ninu nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ni ọjọ́ iwájú, onítọ̀hún ti kọ́ ẹ̀yà kan ninu oògùn, bi èèyàn ba ṣe n kọ́ ọ sí naa ni yoo ṣe maa pọ̀ ni oògùn sí.

فوائد الحديث

Ṣíṣe wiwo ìràwọ̀ ni eewọ, oun naa ni sísọ nípa ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú igbarale àwọn iṣesi ìràwọ̀; torí pé o wa nínú pípe apemọra ìní-ìmọ̀ kọ̀kọ̀.

Wiwo ìràwọ̀ ti o jẹ eewọ wa ninu iran oògùn ti o tako ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan, yatọ si wiwo ìràwọ̀ láti mọ ibudojukọ, tabi ìwọlé àwọn àsìkò ati awọn oṣù, nǹkan ti o tọ́ ni.

Bi o ba ṣe n kọ́ imọ wiwo ìràwọ̀ naa ni o ṣe maa lékún ni kíkọ́ imọ ẹka oògùn.

Irawọ ni anfaani mẹta ti Ọlọhun sọ ninu tira Rẹ: Ọ̀ṣọ́ ni fun sánmọ̀, àmì ni ti a fi n mọ̀nà, ati nǹkan ti a maa n jù mọ́ àwọn èṣù.

التصنيفات

Awọn nnkan ti wọn maa n ba Isilaamu jẹ