Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ

Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ

Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe: "Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ yiyi ibajẹ- oun ni gbogbo nnkan ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ kọ kuro nibẹ- pada, ni ibamu bi ikapa ba ṣe mọ, nitori naa ti o ba ri ibajẹ kan, yiyi i pada pẹlu ọwọ jẹ dandan fun un ti ikapa ba n bẹ fun un, ṣugbọn ti o ba kagara kuro nibi ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ pẹlu pe ki o kọ fun ẹni ti o ba ṣe e ki o si ṣàlàyé inira ti o n bẹ nibẹ fun un, ki o si tọ ọ sọ́nà lọ si ibi daadaa dipo aburu yii, Tí o ba kagara kuro nibi ipo yii, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ pẹ̀lú ki o korira ibajẹ yii, yoo si ni ipinnu pe ti oun ba ni ikapa lori yiyi i pada ni ko ba ṣe bẹẹ, Yiyi pada pẹlu ọkan jẹ eyi ti o lẹ julọ ninu awọn ipo igbagbọ nibi yiyi ibajẹ pada.

فوائد الحديث

Hadisi naa jẹ ipilẹ nibi alaye awọn ipo yiyi ibajẹ pada.

Àṣẹ naa jẹ pẹlu díẹ̀ díẹ̀ nibi kikọ kuro nibi ibajẹ, gbogbo eniyan ni ibamu si odiwọn ini ikapa rẹ ati ini agbara rẹ ni.

Kikọ kuro nibi ibajẹ jẹ abala kan ti o tobi ninu ẹsin ti ko bọ fun ẹnikẹni, ti a la a bọ Musulumi kọ̀ọ̀kan lọrun ni ibamu si ikapa rẹ.

Pipaṣẹ ohun rere ati kikọ kuro nibi ibajẹ wa ninu iwa igbagbọ, ati pe igbagbọ maa n lekun o si maa n dinku.

Wọn ṣe ni majẹmu nibi kikọ kuro nibi ibajẹ: Imọ nipa pe ki ìṣẹ́ yẹn jẹ ibajẹ.

Wọn ṣe ni majẹmu nibi yiyi ibajẹ pada: Ki ibajẹ ti o tobi ju ìyẹn lọ ma jẹ yọ latara rẹ̀.

Àwọn ẹkọ ati awọn majẹmu n bẹ fun kikọ kuro nibi ibajẹ ti o lẹtọọ fun musulumi lati kọ wọn.

Kíkọ ibajẹ bukaata si òṣèlú ti o ba sharia mu, ati imọ ati amọdaju.

Aikọ ibajẹ pẹlu ọkan n tọka sí lilẹ igbagbọ.

التصنيفات

Lilekun igbagbọ ati adinku rẹ, Idajọ pipa àṣẹ pẹlu daadaa ati kikọ kuro nibi iwa ibajẹ, Principles of Enjoining Good and Forbidding Evil