إعدادات العرض
Fun mi ni iro nipa ti mo ba ki awọn irun ọran-anyan, ti mo gba awẹ Ramadan, ti mo ṣe ẹtọ ni ẹtọ, ti mo ṣe eewọ ni eewọ
Fun mi ni iro nipa ti mo ba ki awọn irun ọran-anyan, ti mo gba awẹ Ramadan, ti mo ṣe ẹtọ ni ẹtọ, ti mo ṣe eewọ ni eewọ
Lati ọdọ Jaabir- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju arakunrin kan beere lọwọ Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fun mi ni iro nipa ti mo ba ki awọn irun ọran-anyan, ti mo gba awẹ Ramadan, ti mo ṣe ẹtọ ni ẹtọ, ti mo ṣe eewọ ni eewọ, ti mi ko le nnkan kan kun lori ìyẹn, njẹ maa wọ alujanna? O sọ pe: “Bẹẹni”, o sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura pe mi ko nii le nnkan kan kun lori ìyẹn.
الترجمة
العربية Kurdî English Kiswahili Español اردو Português বাংলা Bahasa Indonesia فارسی தமிழ் हिन्दी සිංහල Tiếng Việt മലയാളം Русский မြန်မာ ไทย پښتو অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands ئۇيغۇرچە Türkçe Bosanski Hausa తెలుగు دری Ελληνικά Azərbaycan Български Fulfulde Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek नेपाली Moore Oromoo Wolof Tagalog Soomaali Français Українська bm Deutsch ქართული Македонски Magyar 中文الشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ki awọn irun ọran-anyan maraarun-un ti ko le nnkankan kun ninu awọn nafila, ti o si gba awẹ Ramadan ti ko gba awọn aṣegbọrẹ, ti o ni adisọkan jijẹ ẹtọ nnkan ẹtọ ti o si ṣe é, ti o ni adisọkan jijẹ eewọ nnkan eewọ ti o si jina si i, dajudaju yoo wọ alujanna.فوائد الحديث
Ojúkòkòrò Musulumi lori ṣíṣe awọn ọran-anyan ati gbigbe awọn eewọ ju silẹ, ati pe ki afojusun rẹ jẹ wiwọ alujanna.
Ṣíṣe pataki ṣíṣe nnkan ẹtọ ati ini adisọkan jijẹ ẹtọ rẹ, ati ṣíṣe nnkan eewọ ni eewọ ati ini adisọkan jijẹ eewọ rẹ.
Ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn nnkan eewọ ju silẹ jẹ okunfa fun wiwọ inu alujanna.