Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika

Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika

Lati ọdọ Abu Humayd tabi lati ọdọ Abu Usayd, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tọka awọn ijọ rẹ sibi adua ti wọn maa ṣe nigba ti wọn ba fẹ wọ masalaasi: (Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika), nigba naa ni yio beere lọwọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ki O ṣe ni irọrun fun un awọn okunfa ikẹ Rẹ, ati pe ti o ba fẹ jade ki o sọ pe: (Allāhummo inni as’aluka min fadlika), nigba naa yio waa bẹ Ọlọhun ninu ọla Rẹ ati alekun daadaa Rẹ ninu jijẹ-mimu halaali.

فوائد الحديث

A fẹ ki a ṣe adua yii nigba ti a ba fẹ wọ masalaasi ati nigba ti a ba fẹ jade kuro nibẹ.

Sisẹsa didarukọ ikẹ nigba ti a ba fẹ wọle, ati ọla nigba ti a ba fẹ jade: Dajudaju ẹni ti o n wọle ko airoju pẹlu nkan ti yio sun un mọ Ọlọhun ati alujanna, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ikẹ, ati pe nigba ti o ba jade yio kaakiri ori ilẹ lati wa ọla Ọlọhun ninu jijẹ-mimu lọ, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ọla.

Awọn asikiri yii a maa n sọ wọn nigba ti a ba gbero lati wọ masalaasi, ati nigba ti a ba gbero lati jade kúrò nibẹ.

التصنيفات

Awọn iranti iwọle ati ijade kuro ninu mọsalasi, Awọn idajọ awọn mọsalasi