?Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti aja ati agogo ba wa pẹlu wọn

?Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti aja ati agogo ba wa pẹlu wọn

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti aja ati agogo ba wa pẹlu wọn ».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju awọn malaika o nii wa pẹlu ikọ arin irin-ajo kan ti aja n bẹ pẹlu wọn, tabi agogo ti wọn maa n gbe kọ ọrun awọn ẹranko ti wọn maa n gùn ti yio maa mu ohun wa ti o ba ti n lọ.

فوائد الحديث

Kikọ kuro nibi nini awọn aja ati mimaa mu wọn lọ si ibi kan, wọn wa yọ kúrò ninu kikọ yii aja ọdẹ tabi aja oluṣọ.

Awọn malaika ti wọn o kọ lati wa pẹlu rẹ ni awọn malaika ikẹ, ṣugbọn awọn malaika oluṣọ awọn o ki n ya awọn ẹrusin ni ile ni tabi ni ajo.

Kikọ kuro nibi agogo; nítorí pé feere kan ni ninu awọn feere satani, o si tun jọ agogo awọn Kristẹni.

O jẹ dandan fun musulumi ki o jina si gbogbo nkan ti o ba jẹ pe o le maa le awọn malaika jina si i.

التصنيفات

Àwọn Malaika