Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom

Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom

Lati ọdọ Thaoban- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n wa aforijin lẹẹmẹta, o maa sọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom”, Al-Waleed sọ pé: Mo sọ fun Al-‘Aozaa’iy: Bawo ni a ṣe maa n wa àforíjìn? O sọ pe: Waa sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah, Astagfirullah. Lẹyin naa o maa gbe Oluwa rẹ tobi pẹlu sisọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikrọọm” Ọlọhun ni Ọba Àlàáfíà ti O pe nibi awọn iroyin Rẹ, ti a fọmọ kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku, ti o si n wa lílà lọdọ Rẹ kuro nibi awọn aburu aye ati ọrun ti ko ki n ṣe lọdọ ẹni ti o yatọ si I, Oun- mimọ ni fun Un- ni daadaa Rẹ pọ ni aye ati ọrun, Ẹni ti O ni titobi ati daadaa.

فوائد الحديث

Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lẹyin irun ati didunni mọ ọn.

Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lati wa pipe adinku to wa nibi ijọsin ati lati dí àáyẹ fun itẹle ati aṣeeto to wa nibẹ.

التصنيفات

Awọn iranti irun