Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)

Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)

Lati ọdọ Āisha iya àwọn mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)».

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Awọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - maa n ri ijagun si oju-ọna Ọlọhun ati biba awọn ọta ja ni iṣẹ ti o fi n lọla julọ, Ni Āisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ṣe awọn naa o nii jagun ni? Ni o wa juwe wọn - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lọ sí ibi jihad ti o lọla julọ fun wọn, oun naa ni hajj atẹwọgba (ti o mọ kanga) eleyii ti o ṣe deedee tira Ọlọhun ati sunnah Anabi, ti o si tun la kuro nibi ẹṣẹ ati ṣekarimi.

فوائد الحديث

Jijagun sí oju-ọna Ọlọhun ninu awọn iṣẹ ti o lọla julọ fún awọn ọkunrin lo wa.

Hajj lọla fun awọn obinrin ju jijagun lọ, ati pe o wa ninu awọn iṣẹ ti o lọla julọ fun wọn.

Awọn iṣẹ maa n ni ọla ju ara wọn lọ ni ibamu si oṣiṣẹ.

O pe hajj ni jihad; nítorí pé ijagun ẹmi ni, o sì tun ko inawo sinu, ati agbara ti ara, nitori naa o jẹ ijọsin ara ati owo gẹgẹ bii jijagun sí oju-ọna Ọlọhun.

التصنيفات

‏Ọla ti n bẹ fun hajj ati Umrah