Ẹni ti o ba jagun lati jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke, oun ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun

Ẹni ti o ba jagun lati jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke, oun ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun

Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere nipa arakunrin ti n jagun ni ti ijẹ akin, ati eyi ti n jagun ni ti ìgbónára, ati eyi ti n jagun ni ti karimi, ewo ninu rẹ ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun? Ni ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Ẹni ti o ba jagun lati jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke, oun ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Wọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere nipa ìyapa erongba awọn jagunjagun: Ẹni ti n jagun ni ti ijẹ akin, ati ẹni ti n jagun ni ti igbonara ati ẹni ti n jagun lati mọ ipo rẹ l'ọdọ awọn eeyan, ewo ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun ninu wọn? Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe dajudaju ẹni ti n jagun si oju-ọna Ọlọhun ni: Ẹni ti n jagun lati jẹ ki o jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke.

فوائد الحديث

Ipilẹ didaa awọn iṣẹ ati aidaa rẹ ni aniyan ati ṣiṣe afọmọ iṣẹ fun Ọlọhun.

Ti o ba jẹ wipe erongba ti eeyan fi ja ogun ni ki gbolohun Ọlọhun o fi leke, ti erongba mìíràn ti o ba ofin mu naa tun wa kún un, gẹgẹ bii kiko ere ogun, dajudaju ìyẹn o lee ko inira ba ipilẹ aniyan.

Lile awọn ọta kuro ni ilú ati awọn aaye ọwọ ninu jijagun sí oju-ọna Ọlọhun lo wa.

Ọla ti o wa nipa awọn olujagun jẹ ẹsa fun ẹni ti o ba jagun ki gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga le baa leke.

التصنيفات

Awọn ẹkọ jijagun soju ọna Ọlọhun