إعدادات العرض
Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn
Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Hausa Kurdî Kiswahili Português සිංහල Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or Tiếng Việt नेपाली Malagasy Kinyarwanda తెలుగు Lietuvių Oromoo Română മലയാളം Nederlands Soomaali Српски Українська Deutsch ಕನ್ನಡ Wolof Moore Shqip ქართული Azərbaycan Magyarالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o fi eniyan mọna ti o si tọka ti o si ṣe awọn eniyan lojukokoro lọ sibi oju ọna kan ti ododo ati daadaa n bẹ nibẹ pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹsan ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu ẹsan olutẹle náà. Ati pe ẹni ti o ba dari ti o si tọka awọn eniyan lọ sibi oju ọna ibajẹ ati aburu, ti ẹṣẹ ati àṣìṣe tabi ti àlámọ̀rí ti ko lẹtọọ n bẹ nibẹ, pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹṣẹ ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn.فوائد الحديث
Ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ sibi imọna, o kere ni tabi o tobi, ati pe dajudaju olupepe naa, iru ẹsan ẹni ti o siṣẹ n bẹ fun un, ati pe ìyẹn wa ninu titobi ọla Ọlọhun ati pipe ọrẹ Rẹ.
Ewu ti o n bẹ fun ipepe lọ sibi anu, o kere ni tabi o tobi, ati pe dajudaju olupepe náà, iru ẹṣẹ ẹni ti o siṣẹ n bẹ fun un.
Ẹsan wa ninu iran iṣẹ, ẹni ti o ba pepe lọ sibi dáadáa, iru ẹsan ẹni ti o ṣe e n bẹ fun un, ẹni ti o ba si pepe lọ sibi aburu, iru ẹṣẹ ẹni ti o ṣe e n bẹ fun un.
O jẹ dandan fun Musulumi lati ṣọ́ra ki wọn ma baa wo o kọṣe pẹlu dida ẹṣẹ rẹ ni gbangba, ti awọn eniyan si n ri i, nitori pe yoo maa da ẹṣẹ pẹlu ẹni ti o ba kọṣe rẹ, koda ki o ma ṣe e lojukokoro lori ìyẹn.
التصنيفات
Adadaalẹ