Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina

Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ọrọ kan, emi naa sọ omiran, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina" emi naa sọ pe: Ẹni ti o ba ku, ti ko si kii n pe akẹgbẹ kan mọ Ọlọhun, o maa wọ alujanna.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe dajudaju ẹni ti o ba yi nnkan kan ninu nnkan ti o jẹ dandan lati jẹ ti Ọlọhun fun ẹni ti o yàtọ̀ si I, gẹgẹ bii pipe ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- tabi wiwa iranlọwọ lọ sọdọ ẹni ti o yàtọ̀ si I, ti o si ku lori rẹ, dajudaju o maa wa ninu awọn ara ina. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ṣalekun pe dajudaju ẹni ti o ba ku ti ko da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, dajudaju ibuṣẹripadasi rẹ ni alujanna.

فوائد الحديث

Adura ṣíṣe jẹ ijọsin wọn ko gbọdọ yi i afi sọ́dọ̀ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.

Ọla ti o n bẹ fun imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, ati pe dajudaju ẹni ti o ba ku lori rẹ maa wọ alujanna, kódà ki wọn fi iya jẹ ẹ lori awọn ẹṣẹ rẹ kan.

Aburu ti o n bẹ fun ẹbọ, ati pe dajudaju ẹni ti o ba ku lori rẹ maa wọ ina.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah