Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira…

Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ

Lati ọdọ Al-Barrohu- ki Ọlọhun yọnu si i-: Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju nini ifẹ awọn Ansar ninu awọn ara Madina, jẹ àmì lori pipe igbagbọ; eleyii rí bẹ́ẹ̀ nitori gbigba iwaju wọn nibi aranṣe Isilaamu ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati gbigbiyanju nibi gbigba awọn Musulumi sile, ati nina awọn dukia wọn ati ẹmi wọn si oju ọna Ọlọhun, ati pe kikorira wọn jẹ ami lori ṣiṣe sobẹ-ṣelu. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ awọn Ansar, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ.

فوائد الحديث

Iṣẹ rere ti o tobi fun awọn Ansar n bẹ nibẹ, ati pe nini ifẹ wọn jẹ ami lori igbagbọ ati bibọra kuro nibi ṣiṣe sobẹ-ṣelu.

Nini ifẹ awọn ayo Ọlọhun ati riran wọn lọwọ jẹ okunfa ifẹ ọlọhun fun ẹru.

Ọla ti o n bẹ fun àwọn ẹni ìṣáájú akọkọ ninu Isilaamu.

التصنيفات

Awọn ipin igbagbọ, Awọn ipin igbagbọ, Ọla ti o n bẹ fun awọn sahaabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn-, Ọla ti o n bẹ fun awọn sahaabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn-