Mo maa n wẹ emi ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa ti awa mejeeji si jẹ ẹni ti o ni janaba lara, o maa n pa mi láṣẹ, ti maa si ro iro, ti o si maa n sunmọ mi ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu,

Mo maa n wẹ emi ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa ti awa mejeeji si jẹ ẹni ti o ni janaba lara, o maa n pa mi láṣẹ, ti maa si ro iro, ti o si maa n sunmọ mi ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu,

Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo maa n wẹ emi ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa ti awa mejeeji si jẹ ẹni ti o ni janaba lara, o maa n pa mi láṣẹ, ti maa si ro iro, ti o si maa n sunmọ mi ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu, o maa n yọ ori rẹ jade si mi ti o si n ṣe ittikaaf, ti maa si fọ̀ ọ́ ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ nipa apakan ninu awọn iṣesi rẹ ti o jẹ ẹsa pẹlu rẹ (Anabi) - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu rẹ ni pe: O maa n wẹ latara janaba pẹlu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa, ti awọn mejeeji si maa n bu omi ninu rẹ papọ. Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sunmọ ọn ti o si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu, ó maa pa a láṣẹ lati bo ara rẹ lati idodo de orunkun, ti o si maa fi ara rò ó laisi ibalopọ. Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ṣe itikaaf ninu mọsalasi, yoo si gbe ori rẹ jade si 'Aaisha yio si wẹ ẹ ti o si wa ninu ile rẹ ni ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu.

فوائد الحديث

Ṣíṣe ki ọkùnrin maa wẹ pẹlu iyawo rẹ lẹtọọ ninu igba kan naa.

Ṣíṣe fifi ara ro ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu lẹtọọ nibi ti o yàtọ̀ si oju ara obinrin, ati pe dajudaju ara rẹ jẹ nnkan ti o mọ.

Ṣíṣe ríró iro ni nnkan ti a fẹ fun un lasiko ifararo o.

Ṣíṣe amulo awọn okunfa ti o maa kọdi eniyan lati ko si nnkan eewọ.

Kikọ pipẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ninu mọsalasi.

Ṣíṣe fifi ọwọ rẹ kan àwọn nnkan, boya eyi ti o tutu ni tabi eyi ti o gbẹ lẹtọọ, ninu ìyẹn ni fifọ irun ati yíyà á.

Dida ibalopọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu awọn ara ile rẹ.

التصنيفات

Ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi igbeyawo ati ibasepo pẹlu awọn ara ile rẹ