إعدادات العرض
Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia
Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia
Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia".
[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tagalog Kurdî Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் සිංහල မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands ئۇيغۇرچە Hausa ไทย دری Akan Български Fulfulde Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda тоҷикӣ O‘zbek नेपाली Moore Azərbaycan Wolof Oromoo Soomaali Українська bm km rn ქართული Македонски Српски yaoالشرح
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa oore-ọfẹ Ọlọhun ati ikẹ Rẹ̀ lori musulumi, tí ó fi jẹ́ pé tí ó bá wà ninu àṣà musulumi pé ó máa ń ṣiṣẹ́ rere kan ní ẹni tó ní alaafia, tí kò sì rinrin ajo, musulumi naa wáá ní awawi kan latara pé ó ṣaisan, kò wá lè ṣe iṣẹ rere naa, tabi pé ó ṣairoju pẹlu irin-ajo, tabi èyíkéyìí ninu awọn awawi; dajudaju wọn maa kọ laada iṣẹ rere naa silẹ fun un ní pípé, bí ẹni pé ó ṣiṣẹ naa ni awọn asiko tó ni alaafia, tí kò sì wà ní irin-ajo.فوائد الحديث
Gbígbòòrò oore-ọfẹ Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ̀.
Rírọni lati maa gbiyanju ṣe awọn ijọsin fun Ọlọhun, kí a sì maa lo awọn asiko wa dáadáa nigba tí a bá wà ní alaafia, tí a sì ráyè.