lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn…

lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan

Lati ọdọ Abu Muslim Al-Khaolaaniy, o sọ pe: Al-Habeeb Al-Ameen sọ fun mi, ṣùgbọ́n ẹni ti mo nífẹ̀ẹ́ si ni, ṣùgbọ́n oun lọdọ mi, o jẹ olufọkantan, 'Awf ọmọ Maalik Al-'Ashja'iiy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: A jẹ lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, mẹ́sàn-án tabi mẹjọ tabi meje, o wa sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A si ṣẹṣẹ ṣe adehun kan tan ni, a sọ pe: A ti ṣe adehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lẹyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A sọ pé: Dajudaju a ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, leyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" O sọ pe: A wa tẹ awọn ọwọ wa, a si sọ pé: A ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan" dajudaju mo ti ri awọn kan ninu awọn ẹni yẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii ni ki ẹni kankan o ba oun mu un.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lọdọ awọn kan ninu saabe, o wa beere lọwọ wọn lẹẹmẹta lati ṣadehun fun un lori idunnimọ awọn àlámọ̀rí kan: Akọkọ: Ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn nnkan ẹkọ Rẹ, ati pe wọn ko gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ikeji: Gbigbe awọn irun maraarun-un ti a ṣe wọn ni ọran-anyan duro ni ọsan ati oru. Ikẹta: Gbigbọ ati Itẹle pẹlu daadaa fun ẹni ti o ba n dari alamọri awọn Musulumi. Ikẹrin: Mimaa sọ gbogbo awọn bukaata wọn kalẹ ti Ọlọhun laini beere nnkan kan nibẹ lọwọ awọn eniyan, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa rẹ ohun rẹ nilẹ pẹlu rẹ. Dajudaju awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ṣiṣẹ pẹlu nnkan ti wọn ṣe adehun le lori, titi ẹni ti o gba hadiisi naa fi sọ pe: Dajudaju mo ri awọn kan ninu awọn saabe wọnyẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii sọ fun ẹni kankan ki o ba òun mu u, bi ko ṣe pe o maa sọkalẹ ti o si maa mu u fun ara rẹ.

فوائد الحديث

Ṣisẹnilojukokoro lori gbigbe bibi awọn eniyan leere ju silẹ, ati jijina si gbogbo nnkan ti wọn n pe ni ibeere, ati rirọrọ kuro lọdọ awọn eniyan koda ki o jẹ nibi àlámọ̀rí ti o kere.

Ibeere ti a kọ kuro nibẹ ni: Ibeere ti o so pọ mọ awọn àlámọ̀rí ti aye, ko de ibi ibeere nipa imọ tabi awọn àlámọ̀rí ẹsin.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah