إعدادات العرض
“Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”
“Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”.
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands ئۇيغۇرچە සිංහල ไทย دری Fulfulde Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek Moore नेपाली Oromoo Wolof Soomaali Български Українська Azərbaycan bm ქართული Македонскиالشرح
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa nipa ọla idide ni oru Laelatul Kọdri ti o maa n wa ni mẹ́wàá ikẹyin ninu oṣù Ramadan, ati pe ẹni ti o ba gbìyànjú ninu ẹ pẹ̀lú ìrun ati adua ati kika Kuraani ati iranti, ni ẹni tí o gba a gbọ́ ati ọla ti n bẹ fun un, ti o si n reti ẹsan Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, ti kii ṣe ti ṣekarimi tabi ṣekagbọmi, wọn maa fi orí àwọn ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in.فوائد الحديث
Ọla ti n bẹ fun oru Laelatul Kọdri, ati ṣisẹnilojukokoro lori idide ninu ẹ.
Wọn ko nii gba àwọn iṣẹ olóore ayafi pẹ̀lú àníyàn òdodo.
Ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ̀; tori pe ẹni tí ó bá dide ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in.