Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun

Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun

Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: “Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, o wa sọ pe: “Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun. Mọ pe ti gbogbo ẹda ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe anfaani fun ọ, wọn ko nii ṣe àǹfààní kankan fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Ọlọhun ti kọ fun ọ. Ati pe ti wọn ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe ipalara fun ọ, wọn ko nii ṣe ipalara fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Allah ti kọ fun ọ. Wọn ti gbé àwọn ìkọ̀wé sókè, àwọn tákàdá si ti gbẹ.”

[O ni alaafia] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé oun kéré nígbà tí oun n gun nǹkan ọ̀gùn pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa sọ pé: Mo maa kọ ẹ ni àwọn nǹkan kan ti Ọlọhun maa jẹ ki wọn ṣe ọ ni anfaani: Ṣọ́ Ọlọhun pẹlu ṣiṣọ àwọn àṣẹ Rẹ̀ ati jíjìnnà si awọn nǹkan tí O kọ̀, ki O maa ri ọ nibi itẹle àṣẹ Rẹ ati awọn iṣẹ ti a fi n sunmọ Ọlọhun, ki O si má ri ọ nibi awọn ìyapa ati ẹṣẹ, tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀san rẹ ni kí Ọlọ́run dáàbò bò ọ lọ́wọ́ nǹkan ìkórìíra ayé àti ọjọ́ ìkẹyìn, yoo sì ràn ọ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rẹ níbikíbi tí o bá lọ. Ti o ba fẹ tọrọ nnkan, Ọlọhun nikan ni ki o bi; tori pe Oun nikan ni O maa n da onibeere lóhùn. Ti o ba fẹ iranlọwọ, Ọlọhun nìkan ni ki o wa iranlọwọ Rẹ̀. Ki o ni amọdaju pe anfaani kankan ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ará ilẹ̀ kójọ lati ṣe ọ ni anfaani ayafi ohun ti Ọlọhun ba kọ fun ẹ, inira kankan ko si lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ara ilẹ̀ kójọ láti fi ìnira kan ọ àyàfi ohun tí Ọlọhun ba ti kádàrá fun ẹ. Ati pe Ọlọhun ti kọ àlámọ̀rí yii, O si kádàrá rẹ ni ibamu si ọgbọ́n àti imọ Rẹ, ko si àyípadà fun nǹkan ti Ọlọhun kọ.

فوائد الحديث

Pataki kikọ àwọn ọmọ kéékèèké ni ọrọ ẹsin bii imọ imu-Ọlọhun-lọkan àti àwọn ẹkọ ati nǹkan ti o yatọ si ìyẹn.

Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ.

Pipaṣẹ igbarale Ọlọhun, ati igbẹkẹle E yatọ si ẹlomiran, Ó sì dára ni Alámòójútó.

Igbagbọ nínú kádàrá ati yiyọnu si i, ati pe Ọlọhun ni O kádàrá gbogbo nǹkan.

Ẹni ti o ba ra àṣẹ Ọlọhun lare, Ọlọhun maa ra oun naa lare, ko si nii ṣọ́ ọ.

التصنيفات

Awọn ipo idajọ ati kadara