“Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin

“Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin

Láti ọ̀dọ̀ Muaawiyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin, olùpín ni mi, Ọlọhun ni n fúnni, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti àṣẹ Ọlọhun yoo fi dé”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fun, O maa fun un ni agbọye ninu ẹsin Rẹ, oun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ni olupin, o maa n pin ohun ti Ọlọhun ba fun un ninu arisiki ati imọ ati awọn nǹkan mìíràn, ati pe ẹni ti n fúnni gan ni Ọlọhun, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n o kii ṣe olohun jẹ okùnfà ti ko lee ṣe anfaani kankan ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti ayé fi maa parẹ”

فوائد الحديث

Titobi ati ọla ti n bẹ fun imọ sharia ati kikọ ọ, ati ṣisẹnilojukokoro lori ẹ.

Diduro ti òdodo gbọdọ wa ninu ijọ yii, ti àwọn ikọ̀ kan ba ti pa á tì, àwọn ikọ̀ mìíràn maa dúró tì í.

Níní agbọye ninu ẹsin wa ninu pe Ọlọhun fẹ oore fun ẹrú rẹ.

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fúnni pẹ̀lú àṣẹ Ọlọhun ati fífẹ́ Rẹ, ati pe ko ni ikapa nǹkan kan.

التصنيفات

Ọla ti n bẹ fun imọ