“Ki n sọ pe: Subhaanallah, wal hamdulillah, wa laa ilaaha illallohu, wallohu akbar, jẹ nnkan ti mọ nifẹẹ sí ju nnkan ti oorun ran le lori lọ”

“Ki n sọ pe: Subhaanallah, wal hamdulillah, wa laa ilaaha illallohu, wallohu akbar, jẹ nnkan ti mọ nifẹẹ sí ju nnkan ti oorun ran le lori lọ”

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ki n sọ pe: Subhaanallah, wal hamdulillah, wa laa ilaaha illallohu, wallohu akbar, jẹ nnkan ti mọ nifẹẹ sí ju nnkan ti oorun ran le lori lọ”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu awọn gbolohun ti wọn tobi yii loore ju aye ati nnkan ti o wa ninu rẹ lọ, awọn naa ni: “Subhaanallah”: Afọmọ ni fun Ọlọhun kuro nibi awọn adinku. “Alhamdulillah”: Ẹyin ni fun Un pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu nini ifẹ Rẹ ati gbigbe E tobi. “Laa ilaaha illallohu”: ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Ọlọhun. “Allahu Akbar”: Ẹni ti O tobi julọ ti O gbọnngbọn ju gbogbo nnkan lọ.

فوائد الحديث

Ṣisẹnilojukokoro lori iranti Ọlọhun, ati pe o jẹ nnkan ti a nifẹẹ ju nnkan ti oorun ran le lori lọ.

Ṣisẹnilojukokoro lori mimaa ṣe iranti lọpọlọpọ; nitori nnkan ti o wa nibẹ bi ẹsan ati ọla.

Igbadun aye kere ati pe awọn adun rẹ maa tan.

التصنيفات

Awọn iranti ti a tuu lẹ