Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ́ ibi lé ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a nibi idajọ (igbẹjọ)

Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ́ ibi lé ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a nibi idajọ (igbẹjọ)

Lati ọdọ Abu Huraira, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ́ ibi lé ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a nibi idajọ (igbẹjọ).

[O ni alaafia] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ ibi ilejina si ikẹ Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn le ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a. Ati pe ninu rẹ naa ni eyiti wọn maa n fun awọn adajọ lati le jẹ ki wọn o ṣe abosi nínú ẹjọ ti wọn n da; ki ẹni ti o fun un le baa de ibi nkan ti o n fẹ lai ni ẹtọ si i.

فوائد الحديث

Sisan abẹtẹlẹ jẹ eewọ, ati gbigba a, ati ṣiṣe alagata nibẹ, ati ṣiṣe ikunlọwọ lori rẹ; latari nkan ti o wa ninu rẹ ni ikunlọwọ lori ibajẹ.

Abẹtẹlẹ wa ninu awọn ẹṣẹ ti o tobi; torí pé dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹbi le ẹni ti n gba a ati ẹni ti n san an.

Ọran nla ni abẹtẹlẹ jẹ ni agbegbe idajọ ati ofin, ẹṣẹ ti o ni agbara si tun ni; latari nkan ti o wa ninu rẹ ni abosi ati ṣiṣe idajọ pẹlu nkan ti o yatọ si nkan ti Ọlọhun sọkalẹ.

التصنيفات

Awọn ẹkọ adajọ