Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ

Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ

Láti ọ̀dọ̀ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni àwọn ife ìmumi odo adágún naa? O sọ pe: “Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ ni alẹ́ ti o ṣókùnkùn ti ko ni ẹsujo, àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí o ba fi wọn mu omi, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ láéláé, omi n dà sínú rẹ lati inú gọ́tà méjì nínú alujanna, ẹni tí ó bá mu nínú rẹ̀, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ, ibu rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ, gígùn rẹ ni odiwọn ohun ti n bẹ láàrin ìlú Hammaan si ìlú Aelah, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, o si dùn ju oyin lọ”

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- búra pe àwọn ife imumi odo adágún rẹ ni ọjọ igbende pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ, Iyẹn maa hàn ni oru ti o ṣókùnkùn ti ko si òṣùpá nínú ẹ; torí pé oru ti o ba ni òṣùpá, àwọn ìràwọ̀ rẹ ki i hàn; torí pé imọlẹ òṣùpá maa bo wọ́n mọlẹ, ati òru ti ko si ẹsujo nibẹ; torí pé bibẹ ẹsujo maa kọdi rírí àwọn ìràwọ̀, Ati pe àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí ó bá mu omi inú rẹ ko nii gbẹ òùngbẹ láéláé, òùngbẹ ti o si maa gbẹ ẹ́ kẹ́yìn nìyẹn, Àti pé odo adágún rẹ, gọ́tà méjì lati inú alujanna n dà sínú rẹ, ìbú rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ; Bákan náà ni àwọn origun odo adágún naa ṣe ri, gígùn rẹ maa ṣe déédéé ohun ti n bẹ laarin Hammaan, ìlú kan ni ti o wa ni ìpínlẹ̀ Balkọọhu ni ilẹ Shaam, titi dé Aelah, ilu kan ni ti a mọ ti o wa ni etí Shaam, Omi adágún naa funfun ju wàrà lọ, itọwo rẹ dùn ju oyin lọ.

فوائد الحديث

Ifi odo adágún rinlẹ pe o n bẹ, ati awọn oríṣiríṣi idẹra ti o wa ninu ẹ.

Titobi odo adágún naa ati gigun rẹ ati ìbú rẹ ati pipọ àwọn ife imumi rẹ.

التصنيفات

Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin.