“Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni

“Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, iná ayé gan ti tó. O sọ pe: “Ina Jahannama ju ti aye lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, gbígbóná ọkọọkan ninu ẹ da gẹgẹ bii gbígbóná iná ayé”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, sọ fun wa pe ina aye yii jẹ ọkan ninu aadọrin awọn ẹya ina Jahannama, Gbígbóná iná ọjọ́ ìkẹyìn lágbára ju gbígbóná iná ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ ṣe déédéé gbígbóná ina ayé. Wọ́n sọ pé: Ìwọ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, iná ayé yìí ti tó láti fi fi ìyà jẹ àwọn ti wọn ba wọ̀ ọ́, O sọ pé: Ina Jahannama ju ina ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ da gẹgẹ bii rẹ nibi gbígbóná gidi gan.

فوائد الحديث

Ikilọ kúrò nibi iná ki awọn èèyàn le jìnnà sí àwọn iṣẹ ti o maa mú èèyàn wọ̀ ọ́.

Titobi ina Jahannama ati iya rẹ, ati gbígbóná gidi gan rẹ.

التصنيفات

Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin., Awọn iroyin alujanna