“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà tí ó bá padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, láti rí ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ọdọ wọn?

“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà tí ó bá padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, láti rí ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ọdọ wọn?

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà tí ó bá padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, láti rí ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ọdọ wọn?” A sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: “Àwọn aaya mẹ́ta tí ọ̀kan nínú yín máa ń ka lori irun rẹ ni oore fun un ju ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra lọ”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹ̀san kika aaya mẹ́ta lori irun; o ni oore ju ki èèyàn o ri ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ilé rẹ lọ.

فوائد الحديث

Àlàyé ọla ti n bẹ fun kika Kuraani ni orí ìrun.

Awọn iṣẹ rere ni oore, wọn ṣi tun maa ṣẹku titi láéláé ju igbadun ayé ti o maa tán lọ.

Ọla yii kò mọ lori kika aaya mẹta nìkan, gbogbo ìgbà ti ẹni tí n kirun ba ti n ṣe alekun nibi kika àwọn aaya nibi irun rẹ ni ẹsan rẹ maa loore fun un ju iye onka wọn ninu ràkúnmí aboyún lọ.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun al-Quraani alapọnle