“Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”

“Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”.

[O daa] [Abu Daud ni o gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé wọn maa sọ fun ẹni ti n ka Kuraani, ti n lo ohun ti o wa ninu rẹ, ti n dunni mọ́ ọn ni kíkà ati híhá, ti o ba ti wọ alujanna- pé: Maa ka Kuraani, ki o si maa gòkè pẹ̀lú ìyẹn nibi awọn ipò alujanna, ki o si maa ke e gẹ́gẹ́ bí o ṣe maa n ke e ni aye pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ ati ifarabalẹ; tori pe ibùgbé rẹ n bẹ nibi opin aaya ti o maa kà.

فوائد الحديث

Ẹsan maa wa ni ibamu si iṣẹ ni ti odiwọn ati bi iṣẹ ba ṣe rí.

Ṣiṣenilojukokoro lori kika Kuraani, ati mimu ojú tó o dáadáa, ati hiha a, ati ìrònú jinlẹ nipa rẹ, ati lílo ohun ti o wa ninu ẹ.

Alujanna ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpele ati ipò, onikuraani maa dé ipò ti o ga julọ ninu ẹ.

التصنيفات

Ọla ti n bẹ fun ìní akolekan si Kuraani, Ọla ti n bẹ fun ìní akolekan si Kuraani, Awọn ọla ti n bẹ fun al-Quraani alapọnle, Awọn ọla ti n bẹ fun al-Quraani alapọnle