Ẹ̀gbà ọrùn kan ti wọn fi okùn ọfà tín-ín-rín ṣe ko gbọdọ ṣẹku ni ọrun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tabi ẹgba ọrun kan afi ki wọn ge e”

Ẹ̀gbà ọrùn kan ti wọn fi okùn ọfà tín-ín-rín ṣe ko gbọdọ ṣẹku ni ọrun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tabi ẹgba ọrun kan afi ki wọn ge e”

Lati ọdọ Abu Bashir Al-Ansari- ki Ọlọhun yọnu si i-: O wa pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni apakan awọn irin ajo rẹ, o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ran ojiṣẹ kan niṣẹ- ti awọn eniyan si wa ninu ibusun wọn pe-: “Ẹ̀gbà ọrùn kan ti wọn fi okùn ọfà tín-ín-rín ṣe ko gbọdọ ṣẹku ni ọrun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tabi ẹgba ọrun kan afi ki wọn ge e”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ni apakan awọn ìrìn-àjò rẹ, ti awọn eniyan wa ni aaye orun wọn ti wọn maa n sun ni ìrìn-àjò wọn ati tẹnti wọn, bayii ni o wa ran ẹnikan si awọn eniyan ki o pa wọn láṣẹ láti gé awọn ẹgba ọrun ti wọn gbé kọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọrun, boya o jẹ eyi ti wọn ṣe latara okun tín-ín-rín ni- tàbí ti wọn ṣe latara nǹkan mìíràn gẹgẹ bii agogo tabi irin ẹsẹ ẹranko, ìyẹn ri bẹẹ; nitori pe wọn maa n gbe e kọ́ ọ lọrun lati fi ṣọ́ra kuro nibi ojúkójú, wọn wa pa wọn láṣẹ lati ge e; nitori ko lee dá aburu padà kuro fun wọn, ati pe anfaani ati inira, ọwọ Ọlọhun nìkan ṣoṣo ni o wa ti ko si orogun fun Un.

فوائد الحديث

Ṣíṣe siso awọn okun ọfà tín-ín-rín ati awọn ẹgba ọrun mọ ọrun ni eewọ lati fi fa anfaani wa tabi lati ti aburu dànù; nitori pe ìyẹn wa ninu ẹbọ.

Siso ẹgba ọrun ti wọn fi nǹkan to yatọ si okun ọfà tín-ín-rín ṣe mọ́ ọrùn ti o ba jẹ ti ọ̀ṣọ́, tabi lati fi da ẹranko, tabi lati fi so ó mọ́lẹ̀, ko si ohun ti o burú nibẹ.

Jijẹ dandan titako aburu bi ikapa ba ṣe mọ.

Jijẹ dandan siso ọkan papọ mọ Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah