Dajudaju wọn n jẹ awọn mejeeji niya lọwọ, wọn o si jẹ wọn niya nitori alamọri nla kan (ni iwoyesi awọn eeyan), ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti kii mọra kuro nibi itọ, amọ ẹnìkejì o jẹ ẹni ti maa n gbé ọrọ ofofo kaakiri

Dajudaju wọn n jẹ awọn mejeeji niya lọwọ, wọn o si jẹ wọn niya nitori alamọri nla kan (ni iwoyesi awọn eeyan), ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti kii mọra kuro nibi itọ, amọ ẹnìkejì o jẹ ẹni ti maa n gbé ọrọ ofofo kaakiri

Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi saare meji kan, ni o wa sọ pe: «Dajudaju wọn n jẹ awọn mejeeji niya lọwọ, wọn o si jẹ wọn niya nitori alamọri nla kan (ni iwoyesi awọn eeyan), ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti kii mọra kuro nibi itọ, amọ ẹnìkejì o jẹ ẹni ti maa n gbé ọrọ ofofo kaakiri» lẹyin naa ni o wa mu imọ ọpẹ tutu o si ya a si meji, ti o si tun ri ẹyọ kọọkan mọ saare kọọkan, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni idi ti o fi ṣe eleyii? O sọ pe: «O ṣee ṣe ki wọn o ṣe iya awọn mejeeji ni fufuyẹ lopin igba ti wọn o ba tii gbẹ (imọ ọpẹ)».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi saare meji kan, ni o wa sọ pe: Dajudaju awọn meji ti wọn ni saare mejeeji yii wọn n jẹ wọn niya lọwọ; ati pe wọn o jẹ wọn niya lori alamọri ti o tobi ni iwoyesi yin, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé o tobi lọdọ Ọlọhun, Ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti ko ni akolekan nipa ṣiṣọ ara rẹ ati aṣọ rẹ kuro nibi itọ nigba ti o ba n gbọ bukaata rẹ, Ati pe ikeji maa n ṣe ofofo laarin awọn eeyan, ti yio wa maa gbe ọrọ ẹni ti o yatọ si i ni erongba ifi-ara-ni ati dida iyapa ati ogun silẹ laarin awọn eeyan.

فوائد الحديث

Ofofo ati gbigbe imọran kuro nibi itọ jusilẹ wa ninu awọn iya ẹṣẹ ati ninu awọn okunfa iya saare.

Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un ṣe isipaya apakan ni awọn nkan ikọkọ - gẹgẹ bii iya saare - lati ṣe afihan àmì jijẹ anabi rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.

Iṣe yii iyẹn ni yiya imọ ọpẹ si meji ati fifi i si ori saare jẹ ẹsa fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; nitori pe dajudaju Ọlọhun ti fi han an ìṣesí awọn ti wọn wa ninu saare naa, nitori naa a ko le fi ẹni ti o yatọ si i (Anabi) ṣe deede rẹ, nitori pe ko si ẹni ti o mọ ìṣesí awọn ti wọn wa ninu saare.

التصنيفات

Isẹmi inu sàréè, Awọn iwa eebu, Awọn ara inu saare