Ẹ jẹ ki saafu yin o dọgba, nitori pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa

Ẹ jẹ ki saafu yin o dọgba, nitori pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa

Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹ jẹ ki saafu yin o dọgba, nitori pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa»

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n pa awọn olukirun láṣẹ lati maa to saafu wọn daadaa, ki apakan wọn si ma yọ siwaju ju apakeji lọ, ki wọn si ma sun sẹyin, ati pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa, ati pe wiwọ saafu si jẹ aayẹ ati adinku ninu rẹ.

فوائد الحديث

Ṣiṣe lofin níní akolekan gbogbo nkan ti o le mu irun pe ti yio si gbe e jina si adinku.

Ọgbọn Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nibi ikọnilẹkọọ, latari bi o ṣe so idajọ papọ mọ okunfa rẹ; ki ọgbọn ṣiṣe ofin le fojú hàn, ati ki awọn ẹmi naa le ji giri lati ṣe amulo ofin.

التصنيفات

Awọn idajọ imam ati ero ẹyin, Awọn idajọ awọn mọsalasi