Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun,

Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun,

Lati ọdọ Ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun, ati ti o ba ti kabara fun rukuu, ati ti o ba gbe ori rẹ dide lati rukuu, o maa gbe mejeeji bákannáà, o si maa sọ pé: "Sami'alloohu liman hamidaHu, Robbanaa wa laKal hamdu", ko ki n ṣe bẹẹ nibi iforikanlẹ.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji soke nibi aaye mẹta ninu irun ni iwájú ejika ti o ṣe pe: Oun ni ibi ti egungun ejika ati apa ti papọ. Aaye akọkọ: Ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun nibi kikabara iwọ irun. Ikeji: Ti o ba ti kabara fun rukuu. Ikẹta: Ti o ba ti gbe ori rẹ sókè lati rukuu, ti o wa sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu Robbanaa wa laKal hamdu. Ko ki n gbe ọwọ rẹ mejeeji sókè nibi ìbẹ̀rẹ̀ fifi ori kanlẹ, tabi nibi gbigbe ori sókè lati ibẹ.

فوائد الحديث

Ninu awọn ọgbọn ti o n bẹ fun gbigbe ọwọ mejeeji soke nibi irun ni pe o jẹ ọṣọ fun irun ati igbetobi fun Ọlọhun- mimọ ni fun Un-.

Gbigbe ọwọ rẹ mejeeji soke fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ rẹ̀ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi aaye ikẹrin gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ẹgbawa Abu Hamid As-Saa'idiy lọdọ Abu Daud ati ẹni ti o yàtọ̀ si i, oun ni nibi idide lati ataya akọkọ nibi irun oni rakah mẹta ati mẹrin.

O fi ẹsẹ rinlẹ bakannaa lati ọdọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe o maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee eti rẹ mejeeji laini fi ọwọ kan an gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ẹgbawa Maalik ọmọ Al-Huwairith ninu sọhihu mejeeji pé: "Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba kabara o maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji sókè titi tí o maa fi ṣe deedee eti rẹ mejeeji pẹlu wọn"

Adapọ laaarin ṣíṣe Sami'alloohu liman hamidaHu ati Robbanaa wa laKal hamdu jẹ ti imam ati oluda-irun-ki nìkan, ṣùgbọ́n ero ẹyin imam maa sọ pé: Robbanaa wa laKal hamdu.

Sisọ pe: "Robbanaa wa laKal hamdu" lẹyin rukuu ni alaafia lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe awọn ọna mẹrin kan ni a le gba sọ ọ, ati pe eleyii jẹ ọkan ninu rẹ, eyi ti o daa julọ ni ki ọmọniyan tọ ipasẹ àwọn agbekalẹ yii, ki o si mu eyi wa ni ẹẹkan, ati òmíràn wa nigba mii.

التصنيفات

Iroyin irun