إعدادات العرض
Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin
Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin
Lati ọdọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Hausa Kurdî Kiswahili Português සිංහල Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە Tiếng Việt ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or नेपाली Malagasy Kinyarwanda తెలుగు Lietuvių Oromoo Română മലയാളം Nederlands Soomaali Српски Українська Deutsch ಕನ್ನಡ Wolof Moore Shqip Magyar ქართული Azərbaycanالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn adari kan maa jẹ lori awọn Musulumi ti wọn ma maa wuwa imọtaraẹninikan pẹlu awọn dukia Musulumi ati eyi ti o yàtọ̀ si i ninu awọn àlámọ̀rí aye, ti wọn ma maa na an gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ, ti wọn ma maa kọ fun awọn Musulumi nibi ẹtọ wọn nibẹ. O si maa waye lati ọwọ wọn, awọn àlámọ̀rí kan ti wọn kọ ninu ẹsin. Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- beere pé: Ki ni awọn maa ṣe nibi isẹsi yẹn? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn pe didana owo wọn ko lee kọ fun yin lati jẹ ki ẹ kọ nnkan ti o jẹ dandan fun yin si wọn ninu gbigbọ ati itẹle, bi ko ṣe pe ki ẹ ṣe suuru ki ẹ si gbọ́ ki ẹ si tẹle,ẹ ko si gbọdọ fa àlámọ̀rí mọ wọn lọwọ, ki ẹ si beere ẹtọ ti o jẹ ti yin lọdọ Ọlọhun, ati pe ki O tun wọn ṣe, ki O si ti aburu wọn ati abosi wọn lọ.فوائد الحديث
Hadiisi naa wa ninu awọn itọka ijẹ anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti o sọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu ìjọ rẹ ti o si ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi o ṣe sọ.
Ṣíṣe lẹtọọ sisọ fun ẹni ti adanwo fẹ kan nípa nnkan ti wọn maa mu ṣẹlẹ̀ si i ninu àdánwò; lati pese ara rẹ kalẹ, ti o ba ti wa de ba a yoo jẹ onisuuru ti o maa reti ẹsan lati ọdọ Ọlọhun.
Idirọmọ Kuraani ati sunnah maa n mu ni jade kuro nibi awọn fitina ati iyapa.
Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbọ ati itẹle fun awọn adari pẹlu daadaa, ati aima jade le wọn lori, ko da ki abosi ṣẹlẹ̀ lati ọdọ wọn.
Lilo ọgbọ́n ati itẹle sunnah ni asiko awọn fitina.
O jẹ dandan fun ọmọniyan lati ṣe ẹtọ ti o jẹ dandan fun un, ko da ki nnkan kan ṣẹlẹ̀ si i ninu abosi.
Ẹri n bẹ nibẹ lori ipilẹ: Ṣíṣe ẹsa eyi ti o rọrun julọ ninu aburu meji tabi eyi ti o fuyẹ julọ ninu inira meji.
التصنيفات
Awọn ojúṣe imam