Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ

Lati ọdọ Abu Hurayra– ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ.

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sin, o maa n: Akọkọ: O maa gbe ọwọ rẹ, tabi aṣọ rẹ sori ẹnu rẹ; ki nnkan kan ma baa jade lati ẹnu rẹ tabi imu rẹ ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ. Ikeji: O maa n rẹ ohun rẹ nilẹ, ko si nii gbe e soke.

فوائد الحديث

Alaye ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi sinsin ati iwo awokọṣe rẹ nibi ìyẹn.

Ṣíṣe gbigbe aṣọ tabi inuju ati nnkan ti o jọ ọ sori ẹnu rẹ ni nnkan ti a fẹ ati sori imu rẹ ki nnkan kan ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ ma baa jade lati ọdọ rẹ nigba ti o ba sin.

Irẹ ohun sinsin silẹ jẹ nnkan ti a fẹ, ó wa ninu pipe ẹkọ, ninu awọn iwa ti o daa si ni.

التصنيفات

Awọn ẹkọ sinsin ati yiyan, Awọn iwa daadaa ti Anabi