“Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà

“Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, ó gba a wá lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a: “Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà, Ọlọhun ti ṣẹbi lé awọn ijọ kan tí wọ́n sọ saare awọn Anabi wọn di mọṣalaṣi”.

[O ni alaafia] [Ahmad ni o gba a wa]

الشرح

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, képe Oluwa rẹ̀ pé kí o má ṣe sọ saare oun dà gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti awọn eniyan n sìn nipa gbigbe titobi fun un ati fífi orí kanlẹ fun un. Lẹhin naa, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, fún wa ní ìró pé Ọlọhun ti gbe ikẹ Rẹ̀ jìnnà sí awọn tí wọ́n sọ saare awọn Anabi di mọṣalaṣi; nitori sísọ ọ di mọṣalaṣi lè di ọna awawi lati jọsin fún wọn, ati níní adiọkan sí wọn.

فوائد الحديث

Títayọ aala ofin sharia nibi saare awọn Anabi ati awọn ẹni rere yoo jẹ ki awọn eniyan maa jọsin fún wọn dipo Ọlọhun, nitori naa, ọranyan ni kí a wá ìṣọra kuro nibi awọn ọna ẹbọ.

Kò tọ́ láti lọ síbi saare nitori gbígbé títóbi fun un ati ṣiṣe ìjọsìn níbẹ̀, bó ti lè wù kí ẹni tí ó wà ninu saare naa sunmọ Ọlọhun Ọba tó.

Eewọ ni kíkọ́ mọṣalaṣi sori àwọn saare.

Eewọ ni kí a máa kírun níbi saare, kódà bí wọn ò bá kọ́ mọṣalaṣi, ayafi kíkí ìrun sí òkú tí wọn ò tíì kirun sí lara.

التصنيفات

Ida ọrọgun pọ mọ Ọlọhun, Ida ọrọgun pọ mọ Ọlọhun, Awọn idajọ awọn mọsalasi, Awọn idajọ awọn mọsalasi