Ma ṣe maa binu

Ma ṣe maa binu

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Arákùnrin kan sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi, o sọ pé: “Ma ṣe maa binu”, o wa pààrà rẹ ni ọpọlọpọ ìgbà, o tun sọ pé: “Ma ṣe maa bínú”.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Ọ̀kan ninu awọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- wá láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o tọka òun si nǹkan kan tí o maa ṣe e ni anfaani, o wa pa a láṣẹ ki o ma maa bínú, itumọ ìyẹn ni pe ki o jìnnà si awọn okùnfà ti o le mu u binu, ki o si ko ara rẹ ni ìjánu ti ìbínú bá ṣẹlẹ̀, ki o ma tẹ síwájú nibi ibinu rẹ pẹlu pípa, tàbí lílù, tabi èébú, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Arákùnrin naa paara wíwá àsọtẹ́lẹ̀ naa ni ọpọlọpọ ìgbà, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko sọ fun un nibi àsọtẹ́lẹ̀ naa ju pe “ma ṣe maa binu”.

فوائد الحديث

Ikilọ kuro nibi ìbínú ati awọn okùnfà rẹ; tori pe oun ni o ko gbogbo aburu sinu, ṣiṣọra kuro nibẹ ni o ko gbogbo oore sínú.

Ibinu nítorí Ọlọhun, gẹgẹ bii ibinu nígbà tí wọ́n bá rú òfin Ọlọhun, eyi wa lara ibinu ti o dára.

Àsọtúnsọ ọ̀rọ̀ sísọ nígbà tí a bá nílò rẹ̀ títí tí olùgbọ́ yóò fi mọ̀ nípa rẹ̀ tí yóò sì mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀.

Ọla ti n bẹ fun wíwá àsọtẹ́lẹ̀ lati ọdọ onimimọ.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin