“Adua naa ni ìjọsìn

“Adua naa ni ìjọsìn

Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Adua naa ni ìjọsìn”, lẹyin naa ni o wa ka: “{Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ} [Gaafir: 60]”.

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé adua naa ni ìjọsìn, ohun ti o jẹ dandan naa ni ki gbogbo ẹ jẹ ti Ọlọhun nìkan, yálà o jẹ adua ibeere ati wiwa nǹkan ni, bii ki o tọrọ lọ́dọ̀ Ọlọhun ohun ti o maa ṣe e ni anfaani, ati titi ohun ti o maa ko inira ba a ni ayé ati ọ̀run lọ, tabi o jẹ adua ìjọsìn, oun ni gbogbo nnkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ti o si yọnu si ninu awọn ọ̀rọ̀ ati awọn iṣẹ ti o han ati eyi ti o pamọ, àwọn ìjọsìn ti ọkàn tabi ara tabi dúkìá. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa mu ẹri wa lori ìyẹn, nibi ti o ti sọ pe: Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ}

فوائد الحديث

Adua ni ipilẹ ìjọsìn, ko tọ́ ki a ṣe e fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun.

Adua kó pàápàá ijẹ-ẹru sínú, ati jijẹwọ ọ̀rọ̀ Olúwa ati ikapa Rẹ, ati ìní bukaata ẹrú si I.

Àdéhùn ìyà ti o le koko ni ẹsan ìgbéraga nipa jijọsin fun Ọlọhun ati gbigbe pipe E ju silẹ, ati pe awọn ti wọn n ṣe ìgbéraga nipa pipe Ọlọhun maa wọ iná Jahannamọ ni ẹni yẹpẹrẹ.

التصنيفات

Ọla ti nbẹ fún adua