Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wa ni khutubal haajah

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wa ni khutubal haajah

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wa ni khutubal haajah: Innal hamda lillah, nasta’eenuhu wa nastagfiruhu, wa na’uudhu bihi min shuruuri anfusinaa, man yahdii llohu falaa mudilla lahu, wa man yudlil fa laa haadiya lahu, wa ash-hadu an laa ilaaha illallohu, wa ash-hadu anna Muhammadan ‘abduhu wa rosuuluhu, (Yaaa ayyuhan naasut taqoo Rabbakumul lazee khalaqakum min nafsinw waahidatinw wa khalaqa minhaa zawjahaa wa bas sa minhumaa rijaalan kaseeranw wa nisaaa’aa; wattaqul laahallazee tasaaa ‘aloona bihee wal arhaam; innal laaha kaana ‘alaikum Raqeeba) (An-Nisa: 1), (Yaaa ayyuhal lazeena aamanut taqul laaha haqqa tuqaatihee wa laa tamootunna illaa wa antum muslimoon) (Aal-Imran: 102), (Yaaa ayyuhal lazeena aamanut taqul laaha wa qooloo qawlan sadeedaa(70) Yuslih lakum a’maalakum wa yaghfir lakum zunoobakum; wa mai yuti’il laaha wa Rasoolahoo faqad faaza fawzan ‘azeemaa) (Al-Ahzab: 70-71).

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Nasaa'iy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Ọmọ Mas’ud - ki Ọlọhun yọnu si i - n sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wọn ni khutubal haajah, oun ni wọn maa n sọ nibi ìbẹ̀rẹ̀ ọrọ nibi khutubah ati níwájú bukaata wọn, gẹgẹ bii khutubah igbeyawo ati khutubah irun Jimoh ati eyi ti o yatọ si wọn, Ati pe khutubah yii ko awọn ìtumọ̀ ti o tobi sinu bii alaye pe Ọlọhun lẹtọọ si gbogbo awọn iran ọpẹ, ati wiwa iranlọwọ lọdọ Rẹ ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati bibo awọn ẹṣẹ ati mimu oju kuro nibẹ, ati sisadi I kuro nibi gbogbo aburu, ati awọn aburu ẹmi ati eyi ti o yatọ si wọn. Lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju imọna ọwọ Ọlọhun ni o wa, ẹni ti O ba fi mọna ko si oluṣini-lọna kan fun un, ẹni ti O ba ṣi lọna ko si atọnisọna kan fun un. Lẹyin naa o darukọ ijẹrii imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo pe oun ni pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, ati pe ijẹrii iṣẹ́-rírán ni pe dajudaju Muhammad jẹ ẹrusin Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ. O pari khutubah yii pẹlu awọn aayah mẹta ti wọn ko àṣẹ pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sinu pẹlu ṣiṣe awọn àṣẹ Rẹ ati jijina si awọn nǹkan ti Ó kọ̀ lati fi wa oju rere Ọlọhun, ati pe dajudaju ẹsan ẹni ti o ba ṣe iyẹn ni dídára awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ati pipa awọn aburu rẹ ati aforijin awọn ẹṣẹ ati iṣẹmi ti o mọ ni aye ati erenjẹ pẹlu alujanna ni ọjọ igbedide.

فوائد الحديث

Ṣiṣe bibẹrẹ awọn khutubah igbeyawo ati ti irun jimọh ati eyi ti o yatọ si wọn pẹlu khutubah yii ni nnkan ti a fẹ.

Khutubah lẹtọọ lati ko ọpẹ sinu ati ijẹrii mejeeji ati awọn aayah Kuraani kan.

Kikọ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n kọ́ àwọn saabe ni nnkan ti wọn bukaata si ninu ẹsin wọn.

التصنيفات

‏Awọn idajọ ati majẹmu igbeyewo