إعدادات العرض
Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun
Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: "Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, o sọ pe: Aga ọla Rẹ wa ni ori omi".
[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Español Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe Bosanski සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Kurdî Hausa മലയാളം తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া Shqip دری Ελληνικά Български Fulfulde Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek नेपाली Moore Oromoo Wolof Soomaali Tagalog Français Azərbaycan Українська bm தமிழ் Deutsch ქართული Português Македонски فارسی Magyar Lingala Русский 中文الشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun kọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kadara awọn ẹda ni ifọsiwẹwẹ ninu isẹmi ati iku ati arisiki ati nnkan ti o yatọ si ìyẹn sinu Wàláà ti A n ṣọ ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, ti yoo maa ṣẹlẹ̀ ni ibamu si nnkan ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ti kadara, Gbogbo nnkan ti o n bẹ n bẹ pẹlu idajọ Ọlọhun ati kadara Rẹ, Nnkan ti o ba ṣẹlẹ̀ si ẹru wọn ti kọ ọ pe ko nii fo o ru, nnkan ti o ba fo o ru wọn ti kọ ọ pe ko nii ṣẹlẹ̀ si i ni.فوائد الحديث
Jijẹ dandan nini igbagbọ ninu idajọ ati kadara.
Kadara ni: Imọ Ọlọhun nipa gbogbo nnkan ati kikọ wọn Rẹ ati fifẹ Rẹ ati dida Rẹ ti O da wọn.
Nini igbagbọ pe awọn kadara jẹ nnkan ti wọn kọ ṣíwájú dida sanmọ ati ilẹ, ìgbàgbọ́ yii maa ṣeso iyọnu ati jijupa-jusẹ silẹ.
Dajudaju aga ọla Ọba Ajọkẹ-aye wa lori omi ṣíwájú dida sanmọ ati ilẹ.
التصنيفات
Awọn ipo idajọ ati kadara