“Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”

“Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”

Láti ọ̀dọ̀ Uqbah ọmọ Aamir Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”.

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ẹni ti ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni tí n kéde sàárà ṣíṣe, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni tí n fi sàárà pamọ.

فوائد الحديث

Kika Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ ni o ni ọlá jù, gẹgẹ bi fifi sàárà pamọ naa ṣe ní ọlá jù; tori imọkanga ti o wa nibẹ, ati ijinna si ṣekarimi ati motomoto, àyàfi tí bukaata tabi anfaani ba pepe lọ sibi ki a ka a sókè, gẹgẹ bii kikọ èèyàn ni Kuraani.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun al-Quraani alapọnle, Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ awọn ọkan, Awọn ẹkọ kika al-Quraani alapọnle