Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa

Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: «Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n kilọ fun ẹni ti o ba da oju ija kọ awọn Musulumi pẹlu nnkan ìjà, lati le dẹru ba wọn ati lati fi tipa gba nkan wọn, nitori naa ẹni ti o ba ṣe ìyẹn lai lẹtọọ, o ti da ọran nla ati ẹṣẹ nla kan ninu awọn iya ẹṣẹ, ti o si lẹtọọ si adehun iya ti o le.

فوائد الحديث

Ikilọ ti o le kuro nibi ki Musulumi o ba awọn ọmọ-iya rẹ Musulumi ja.

Ninu awọn ibajẹ ti o tobi julọ ni orilẹ ni yiyọ nkan ija si awọn Musulumi, ati ṣiṣe ibajẹ pẹlu ipaniyan.

Adehun iya ti wọn sọ yẹn ko ko ìjà pẹlu ẹtọ sinu, gẹgẹ bii biba awọn olutayọ ala ati awọn aṣebajẹ ati awọn ti o yatọ si wọn ja.

Ṣiṣe idẹruba awọn Musulumi pẹlu nkan ija tabi eyi ti o yatọ si i ni eewọ– koda ki o jẹ ni ọna awada -.

التصنيفات

Pooki, Ijiya awọn danadana