Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ

Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ

Lati ọdọ Abu Sa‘ēd Al-khudriyy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣeni lojukokoro lori jijẹ ipe oluperun nigba ti a ba n gbọ ọ, ati pe ìyẹn ni ki a maa sọ nkan ti o n sọ, ni gbolohun gbolohun. Nigba ti o ba wa sọ gbolohun Allāh Akbar àwa naa o wi i lẹyin rẹ, ati pe nigba ti o ba mu gbolohun ijẹrii mejeeji wa, awa naa o mu un wa lẹ́yìn rẹ, Ati pe wọn ṣe ayaafi gbolohun: (Hayya ‘alas sọlāt, Hayya ‘alal falāh) wọn maa sọ lẹyin awọn mejeeji pe: lā haola walā quwwata illā biLlāh.

فوائد الحديث

Yio maa tẹle oluperun keji lẹyin ti alakọkọọ ba pari, koda ki awọn oluperun o pọ! Latari kikari hadīth yii.

Yio maa jẹ ipe oluperun (yio maa sọ nkan ti o ba n sọ) ni gbogbo iṣesi rẹ, ti ko ba ti si ni ile ẹgbin tabi lori bukaata rẹ (itọ tabi igbẹ).

التصنيفات

Irun pipe ati Iqoomoh